Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  October 2016

October 3 sí 9

ÒWE 1-6

October 3 sí 9
 • Orin 37 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Fi Gbogbo Ọkàn-àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”: (10 min.)

  • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe.]

  • Owe 3:1-4—Ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kó o sì jẹ́ olóòótọ́ (w00 1/15 ojú ìwé 23 àti 24)

  • Owe 3:5-8—Ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà (w00 1/15 ojú ìwé 24)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Owe 1:7—Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀”? (w06 9/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1; it-2-E ojú ìwé 180)

  • Owe 6:1-5—Ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání wo la lè gbé tá a bá rí i pé a ti ṣe àdéhùn tí kò mọ́gbọ́n dání lórí ọ̀rọ̀ okòwò? (w00 9/15 25-26)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Owe 6:20-35

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Jákèjádò ayé, a máa pé àwọn èèyàn láti wá sáwọn ìpàdé wa ní òpin ọ̀sẹ̀, gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kópa kíkún nínú iṣẹ́ yìí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 107

 • Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (8 min.) Ẹ sì lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 ojú ìwé 25 sí 27)

 • Máa Hùwà Rere Sáwọn Tó Wá sí Àwọn Ìpàdé Wa (Owe 3:27): (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? Lẹ́yìn náà béèrè pé báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lóṣù October àti ní gbogbo ìgbà.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 12

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 143 àti Àdúrà