Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Máa Dáhùn Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Bá A Ṣe Lè Máa Dáhùn Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Ìdáhùn tó gbéṣẹ́ máa ń gbé ìjọ ró. (Ro 14:19) Ó sì máa ṣe ẹni tó dáhùn náà láǹfààní. (Owe 15:23, 28) Torí náà, ó yẹ ká máa gbìyànjú láti dáhùn nípàdé ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan. Òótọ́ ni pé wọ́n lè má pè wá ní gbogbo ìgbà tá a bá nawọ́. Fún ìdí yìí, ó yẹ ká máa múra ju ìdáhùn kan lọ.

Ìdáhùn tó gbéṣẹ́ . . .

  • máa ń ṣe tààràtà, kì í lọ́jú pọ̀, á sì ṣe ṣókí, láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀

  • máa ń jẹ́ ìdáhùn lọ́rọ̀ ara ẹni

  • kì í ṣe àtúnsọ ohun tẹ́nì kan ti dáhùn tẹ́lẹ̀

Tó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n kọ́kọ́ pè, . . .

  • dáhùn ìbéèrè náà ní tààràtà, kó sì ṣe ṣókí

Bí ẹnì kan bá ti dáhùn ṣáájú, o lè . . .

  • fi ẹsẹ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀ ti kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò lẹ́yìn

  • sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò ní ìgbésí ayé wa

  • ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìsọfúnni náà

  • sọ ìrírí ṣókí láti kín kókó pàtàkì náà lẹ́yìn