JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Àwọn kan ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Jésù wà, ó sì dá àwọn míì lójú gbangba pé Jésù wà. Àwọn míì sì sọ pé kò sí bí èèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá Jésù wà tàbí kò sí. Kí lèrò yín?

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù wà lóòótọ́.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?

Ka Bíbélì: Jo 11:11-14

Òtítọ́: Téèyàn bá kú, ó ti tán nìyẹn. Torí náà, kò sídìí láti máa bẹ̀rù pé èèyàn máa lọ jìyà níbì kan. Jésù sọ pé ńṣe ni ikú dà bí ìgbà téèyàn sùn. Bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde, ó lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú náà dìde, kí wọ́n lè pa dà gbádùn ìgbésí ayé wọn.Job 14:14.

ÌWÉ ÌKÉSÍNI SÍ ÀWỌN ÌPÀDÉ ÌJỌ (inv)

Fi ìwé lọni: Mo fẹ́ pè yín láti wá gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì, ọ̀fẹ́ ni o. Ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yín la ti máa ṣe é. [Fún un ní ìwé ìkésíni, sọ àkókò àti àdírẹ́sì ibi tẹ́ ẹ ti máa ń ṣe ìpàdé ní òpin ọ̀sẹ̀, kó o sì sọ àkòrí àsọyé tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn.]

Béèrè ìbéèrè: Ṣé ẹ ti lọ sí ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí? [Tó bá ṣeé ṣe, fi fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ