Jèhófà mú kí wọ́n kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ sínú Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí a lè rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ lára wọn. (Ro 15:4) Kí lo rí kọ́ nínú ìwé Jónà? Wo fídíò náà Ìjọsìn Ìdílé: Jónà​—Kọ́ Bí O Ṣe Lè Jẹ́ Aláànú Bíi Ti Jèhófà, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ìṣòro wo ni àwọn akéde mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nínú fídíò yẹn ní?

  • Báwo ni ìwé Jónà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá bá wa wí tàbí tá a pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan? (1Sa 16:7; Jon 3:1, 2)

  • Báwo ni ìwé Jónà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dáa nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? (Jon 4:11; Mt 5:7)

  • Báwo ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà ṣe lè tù wá nínú nígbà tá a bá ń ṣàìsàn tó le koko? (Jon 2:1, 2, 7, 9)

  • Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ nínú fídíò yìí nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ka Bíbélì ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí?