Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  November 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÁMÓSÌ 1-9

“Wá Jèhófà, Kí O sì Máa Wà Láàyè Nìṣó”

“Wá Jèhófà, Kí O sì Máa Wà Láàyè Nìṣó”

5:6, 14, 15

Kí ló túmọ̀ sí láti wá Jèhófà?

  • Ó túmọ̀ sí pé ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọn kò wá Jèhófà mọ́?

  • Wọ́n dẹni tí kò ‘kórìíra ohun búburú mọ́, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere’

  • Bí wọ́n á ṣe tẹ́ ara wọn lọ́rùn ni wọ́n ń lé

  • Wọn kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà

Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ti pèsè fún wa tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa wá a?