Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  November 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NÁHÚMÙ 1–HÁBÁKÚKÙ 3

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó

Hab 1:5, 6

Bí wọ́n ṣe kìlọ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa pa ilẹ̀ Júdà run lè dá bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀. Torí pé nígbà yẹn, ilẹ̀ Júdà gbára lé orílẹ̀-èdè Íjíbítì tó jẹ́ alágbára. Àwọn ará Kálídíà ò sì lágbára tó orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Láfikún sí èyí, àwọn Júù ò gbà pé Jèhófà lè fàyè gbà á kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpílì rẹ̀ run. Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ṣẹ, Hábákúkù sì gbọ́dọ̀ wà lójúfò kó sì máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà lọ.

Kí ló mú kó dá mi lójú pé ìparí ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé?

Báwo ni mo ṣe lè wà lójúfò kí n sì máa sin Jèhófà nìṣó?