Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Àyípadà ò lè ṣe kó má ṣẹlẹ̀, pàápàá jù lọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (1Kọ 7:31) Bóyá a retí àyípadà kan tàbí ó ṣẹlẹ̀ lójijì, bóyá àyípadà náà dára tàbí kò dára, ó lè mú ká dẹni tí kò ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́, kó sì tún ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí ká sì tún máa tẹ̀ síwájú nígbà tí àyípadà bá ṣẹlẹ̀? Wo fídíò A Wà Láàyè Nípa Tẹ̀mí, Bá A Tiẹ̀ Ṣí Lọ Síbòmíì, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ìmọ̀ràn wo ni arákùnrin kan fún bàbá yẹn?

  • Báwo ni ìlànà tó wà ní Mátíù 7:25 ṣe bá ipò ìdílé yẹn mu?

  • Báwo ni ìdílé yẹn ṣe múra sílẹ̀ kí wọ́n tó kó lọ, báwo ni èyí sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Kí ló ran ìdílé yìí lọ́wọ́ kí ara wọn lè mọlé ní ìjọ tuntun tí wọ́n wà àti àdúgbò tuntun tí wọ́n kó lọ?

Àwọn àyípadà pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ sí mi láìpẹ́ yìí:

Báwo ni mo ṣe lè lo àwọn ìlànà tó wà nínú fídíò yìí?