Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Akéde kan ń fi ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ lọni ní orílẹ̀-èdè Jọ́jíà

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI November 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Wá Jèhófà, Kí O sì Máa Wà Láàyè Nìṣó”

Kí ló túmọ̀ sí láti wá Ọlọ́run? Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọ̀ láti wá Jèhófà?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—⁠Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò

Báwo lo ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́nà tó gbéṣẹ́? Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ní ohun kan pàtó tó o fẹ́ bá a sọ, má sì gbàgbé pé ńṣe lo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ

Ìtàn Jónà fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run kì í pa wá tì tá a bá ṣe àṣìṣe, àmọ́ ó fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe wa.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Ìwé Jónà

Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà, ó máa jẹ́ ká lè fara dà á tí nǹkan ò bá rí bá a ṣe rò, á jẹ́ ká ní èrò tó dára nípa iṣẹ́ ìwàásù wa, á sì jẹ́ ká lè máa fi àdúrà tu ara wa nínú nígbà ìṣòro.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?

Ṣé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tá ò bá ṣe dáadáa sáwọn ará wa?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó

Bí wọ́n ṣe kìlọ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa pa ilẹ̀ Júdà run lè dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ṣẹ, Hábákúkù sì gbọ́dọ̀ wà lójúfò bó ṣe ń retí rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Tí àyípadà kan bá ṣẹlẹ̀ tí kò jẹ́ ká ráyè sin Jèhófà dáadáa mọ́, débi pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ò tún lágbára mọ́, kí ló lè jẹ́ ká wà lójúfò ká sì máa sin Jèhófà nìṣó?