Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  November 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

‘Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè’

‘Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè’

Tí ọkùnrin kan bá ní aya tó dáńgájíá, ó máa ń hàn nínú ìrísí ọkùnrin náà. Nígbà ayé Lémúẹ́lì Ọba, “ẹni mímọ̀” ni ọkọ obìnrin tó dáńgájíá máa ń jẹ́ “ní àwọn ẹnubodè.” (Owe 31:23) Lóde òní, àwọn ọkùnrin tá a bọ̀wọ̀ fún ló máa ń sìn nípò alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Tí wọ́n bá ti níyàwó, ìwà rere àti ìtìlẹ́yìn ìyàwó wọn ló máa jẹ́ kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní yìí. (1Ti 3:4, 11) Àwọn ọkùnrin tó nírú ìyàwó bẹ́ẹ̀ máa ń mọyì ìyàwó wọn gan-an, àwọn ará ìjọ náà sì máa ń mọyì wọn.

Ìyàwó tó dáńgájíá máa ń jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nípa ṣíṣe àwọn nǹkan yìí . . .

  • ó máa ń sọ̀rọ̀ rere láti fún ọkọ rẹ̀ níṣìírí.Owe 31:26

  • ó máa ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tinútinú kí ó lè bójú tó àwọn iṣẹ́ ìjọ.1Tẹ 2:7, 8

  • ó máa ń gbé ìgbé ayé ṣe bí o ti mọ.1Ti 6:8

  • kì í béèrè àwọn àṣírí ìjọ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.1Ti 2:11, 12; 1Pe 4:15