Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  November 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 27-31

Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe

Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe

Ìyá Lémúẹ́lì Ọba fún un ní ìsọfúnni tó ṣe tààrà nípa ojúṣe ìyàwó tó dáńgájíá nínú Òwe orí 31. Ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání yìí jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ ohun tó máa fi dá obìnrin tó dáńgájíà tó ṣeé fi ṣe ìyàwó mọ̀.

Ìyàwó tó dáńgájíá jẹ́ ẹni téèyàn lè fọkàn tán

31:10-12

  • Ó máa ń mú àbá tó wúlò wá nípa àwọn ohun tó ń lọ nínú ìdílé, síbẹ̀ ó máa ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀

  • Ọkọ rẹ̀ gbọ́kàn lé e pé ó máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, torí náà ọkọ rẹ̀ kì í sọ pé dandan ni kó kọ́kọ́ gba àṣẹ lọ́wọ́ òun kó tó lè ṣe ohunkóhun

Ìyàwó tó dáńgájíá máa ń ṣiṣẹ́ kára

31:13-27

  • Ó mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, kì í sì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ, kí àwọn ará ilé rẹ̀ lè máa wọṣọ tó bójú mu, kí wọn sì ní oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ

  • Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì máa ń bójú tó agbo ilé rẹ̀ tọ̀sán tòru

Ó jẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀

31:30

  • Ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀