Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  November 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ONÍWÀÁSÙ 1-6

Gbádùn Gbogbo Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

Gbádùn Gbogbo Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

Jèhófà fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ wa, ó sì kọ́ wa ní ohun tá a lè ṣe láti gbádùn iṣẹ́ wa. Èèyàn lè gbádùn iṣẹ́ rẹ̀ tó bá kọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ náà.

O lè gbádùn iṣẹ́ rẹ tó o bá ń . . .

3:13; 4:6

  • fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ náà

  • ronú nípa bí iṣẹ́ rẹ ṣe ń ṣe àwọn míì láǹfààní

  • ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, àmọ́ tó o bá ti kúrò níbi iṣẹ́, pọkàn pọ̀ sórí ìdílé rẹ àti ìjọsìn rẹ