ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Tí ẹnì kan bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé báwo ni ọ̀run ṣe rí, kí lo máa sọ?

Ka Bíbélì: Jo 8:23

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Jésù àti Bàbá rẹ̀ sọ nípa ọ̀run.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o gbà pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí ni asọtẹ́lẹ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí dá lé?

Ka Bíbélì: 2Ti 3:1-5

Òtítọ́: Níwọ̀n bí àwọn asọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ti ń ṣẹ báyìí, ó dá wa lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó sọ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa náà máa ṣẹ.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?  (Fídíò)

Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀: À ń fi fídíò yìí han àwọn èèyàn láti ṣàlàyé ibi tá a ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì ní ìgbésí ayé. [Jẹ́ kó wo fídíò náà.]

Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ bí Ọlọ́run á ṣe yanjú gbogbo ìṣòro tó wà láyé yìí. [Fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọ̀ ọ́.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.