Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 44-48

Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ”

Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ”

45:2-5

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìjòyè kan tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ni Bárúkù, ìdílé ọba ló sì ti wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkàntọkàn ló fi ń sin Jèhófà, tó sì ń ti Jeremáyà lẹ́yìn, ìgbà kan wà tí kò fọkàn sí àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í “wá àwọn ohun ńláńlá.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó fẹ́ túbọ̀ di olókìkí láàfin ọba tàbí kó jẹ́ pé ó fẹ́ di olówó rẹpẹtẹ. Àmọ́, tó bá máa la ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù já, ó yẹ kó tún èrò rẹ̀ ṣe.