Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2017

May 8-​14

Jeremáyà 35-38

May 8-​14
 • Orin 33 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ebedi-mélékì Jẹ́ Onígboyà àti Onínúure”: (10 min.)

  • Jer 38:​4-6​—Ìbẹ̀rù èèyàn mú Sedekáyà, ó sì fọwọ́ sí i pé kí àwọn alátakò ju Jeremáyà sínú kòtò ẹlẹ́rẹ̀ kó lè kú síbẹ̀ (it-2 1228 ¶3)

  • Jer 38:​7-10​—Ebedi-mélékì lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti ran Jeremáyà lọ́wọ́ (w12 5/1 31 ¶2-3)

  • Jer 38:​11-13​—Ebedi-mélékì jẹ́ onínúure (w12 5/1 31 ¶4)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Jer 35:19​—Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún àwọn ọmọ Rékábù? (it-2 759)

  • Jer 37:21​—Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó Jeremáyà, báwo nìyẹn ṣe lè fún wa níṣìírí nígbà ìṣòro? (w98 1/15 18 ¶16-17; w95 8/1 5 ¶5-6)

  • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

  • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 36:27–37:2

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 127

 • Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa: (15 min.) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wo fídíò náà Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa, tẹ́ ẹ sì ti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń ṣojú ìjọ yín nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Tí ìjọ yín ò bá ní ẹni tó ń ṣojú fún yín, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé ìjọ yín nìkan ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń bójú tó àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba.) Àwọn àtúnṣe wo lẹ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láìpẹ́ yìí, kí lẹ sì tún ń gbèrò láti ṣe? Tí ẹnì kan bá mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe tàbí tó bá fẹ́ máa ran àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe, kí ni ẹni náà máa ṣe? Báwo ni tọmọdé tàgbà wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, láìka ipò yòówù ká wà?

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 12 ¶9-15, àwọn àpótí “Bí Ìtẹ̀síwájú Ṣe Bá Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Ṣe Iṣẹ́ Àbójútó” àti “Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 125 àti Àdúrà