Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 39-43

Jèhófà Máa San Olúkúlùkù Lẹ́san Níbàámu Pẹ̀lú Iṣẹ́ Rẹ̀

Jèhófà Máa San Olúkúlùkù Lẹ́san Níbàámu Pẹ̀lú Iṣẹ́ Rẹ̀

Sedekáyà ṣàìgbọ́ràn sí Jèhófà, ó kọ̀ láti fi ara rẹ̀ sábẹ́ Bábílónì

39:4-7

  • Ìṣojú Sedekáyà ni wọ́n ṣe pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́ ojú rẹ̀, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, wọ́n fi sí ẹ̀wọ̀n ní Bábílónì, ibẹ̀ ló sì kú sí

Ebedi-mélékì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó tún tọ́jú Jeremáyà wòlíì Jèhófà

39:15-18

  • Jèhófà sọ pé òun máa dáàbò bo Ebedi-mélékì nígbà tí Júdà bá pa run

Jeremáyà fìgboyà wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún kí Jerúsálẹ́mù tó pa run

40:1-6

  • Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà nígbà táwọn ọ̀tá gbógun ti Jerúsálẹ́mù, ó sì mú kí àwọn ará Bábílónì tú u sílẹ̀