Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

ILÉ ÌṢỌ́

Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀: Ìwé Ìfihàn tó wà nínú Bíbèlì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan. Ìran yẹn máa ń ba àwọn kan lẹ́rù, àmọ́ ó máa ń ṣe àwọn míì ní kàyéfì.

Ka Bíbélì: Iṣi 1:3

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ bá a ṣe lè jàǹfààní nínú bí àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin náà ṣe ń gẹṣin.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Ṣẹ́ ẹ rò pé a lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Ka Bíbélì: Ais 46:10

Òtítọ́: Ọlọ́run jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

ÌDÍLÉ RẸ LÈ JẸ́ ALÁYỌ̀

Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀: À ń fi fídíò kékeré tó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé yìí han àwọn èèyàn. [Fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ fídíò Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ hàn án.]

Fi ìwé lọni: Tẹ́ ẹ bá fẹ́ ka ìwé tí fídíò yẹn sọ̀rọ̀ nípa ẹ, mo lè fún un yín ní ọ̀kan lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí kí n fi bẹ́ ẹ ṣe lè wà á jáde lórí ìkànnì hàn yín.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ