Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 1-10

Tá A Bá Fẹ́ Wà Ní Àlááfíà Pẹ̀lú Jèhófà, A Ní Láti Bọ̀wọ̀ fún Jésù Ọmọ Rẹ̀

Tá A Bá Fẹ́ Wà Ní Àlááfíà Pẹ̀lú Jèhófà, A Ní Láti Bọ̀wọ̀ fún Jésù Ọmọ Rẹ̀

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn alákòóso máa kórìíra Jèhófà àti Jésù

2:1-3

  • Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè kò ní tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n gbà pé ọwọ́ àwọn làṣẹ ṣì wà

  • Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí Jésù wà láyé, ó sì ń ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lóde òní

  • Onísáàmù náà sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ń sọ nǹkan òfìfo, tó túmọ̀ sí pé pàbó ni ohun tí wọ́n ní lọ́kàn máa já sí, kò lè yọrí sí rere

Awọn tó bá bọ̀wọ̀ fún Ọba tí Jèhófà fòróró yàn nìkan ni yóò ní ìyè

2:8-12

  • Gbogbo àwọn tó bá ta ko Mèsáyà Ọba máa pa run

  • Àwọn tó bá ń bọ̀wọ̀ fún Ọmọ, ìyẹn Jésù yóò rí ààbò àti àlàáfíà