Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 26-33

Bẹ Jèhófà Pé Kó Jẹ́ Kó O Ní Ìgboyà

Bẹ Jèhófà Pé Kó Jẹ́ Kó O Ní Ìgboyà

Dáfídì túbọ̀ ní ìgboyà nígbà tó rántí bí Jèhófà ṣe gbà á sílẹ̀ láwọn ìgbà kan

27:1-3

  • Jèhófà gba Dáfídì sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún nígbà tó wà lọ́mọdé

  • Jèhófà jẹ́ kí Dáfídì pa béárì kan kó lè dáàbò bo agbo ẹran rẹ̀

  • Jèhófà ti Dáfídì lẹ́yìn nígbà tó pa Gòláyátì

Kí ló máa jẹ́ ká ní ìgboyà bíi ti Dáfídì?

27:4, 7, 11

  • Àdúrà

  • Iṣẹ́ ìwàásù

  • Lílọ sí ìpàdé

  • Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé

  • Fífún àwọn ẹlòmíì níṣìírí

  • Ká máa rántí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà kan