Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2016

May 30 sí June 5

SÁÀMÙ 26-33

May 30 sí June 5
 • Orin 23 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Bẹ Jèhófà Pé Kó Jẹ́ Kó O Ní Ìgboyà”: (10 min.)

  • Sm 27:1-3—A máa ní ìgboyà tí a bá ń ronú lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà jẹ́ ìmọ́lẹ̀ wa (w12 7/15 ojú ìwé 22 àti 23 ìpínrọ̀ 3 sí 6)

  • Sm 27:4—Ìmọrírì tá a ní fún ìjọsìn tòótọ́ á máa fún wa lókun (w12 7/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 7)

  • Sm 27:10—Jèhófà ṣe tán láti ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà táwọn èèyàn míì bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀ (w12 7/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9 àti 10)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Sm 26:6—Bíi ti Dáfídì, báwo la ṣe ń rìn yí ká pẹpẹ Jèhófà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ? (w06 5/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 11)

  • Sm 32:8—Àǹfààní wo la máa rí tí Jèhófà bá fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye? (w09 6/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sáàmù 32:1–33:8

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) kt—Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún onílé lórí fóònù tàbí tablet rẹ.

 • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi fídíò náà Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? tó wà lórí JW Library rẹ ṣe àṣefihàn bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé. Jẹ́ kí ẹni náà wo fídíò yìí.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jl ẹ̀kọ́ 9—Ní ṣókí, fi han ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe lè fi JW Library múra ìpàdé sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI