Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2016

May 23 sí 29

SÁÀMÙ 19-25

May 23 sí 29
 • Orin 116 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Jẹ́ Ká Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Mèsáyà”: (10 min.)

  • Sm 22:1—Ó máa dà bíi pé Ọlọ́run ti fi Mèsáyà sílẹ̀ (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16)

  • Sm 22:7, 8—Wọ́n máa kẹ́gàn Mèsáyà (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 13)

  • Sm 22:18—Wọ́n máa ṣẹ́ kèké lé aṣọ Mèsáyà (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 14)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Sm 19:14—Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w06 5/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 8)

  • Sm 23:1, 2—Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa? (w02 9/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sáàmù 25:1-22

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh—Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún onílé lórí fóònù tàbí tablet rẹ.

 • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh—Fi ohun tá a lè fi ṣe ìwádìí, tó wà nínú JW Library wá ẹsẹ Bíbélì kan tó dáhùn ìbéèrè tí onílé béèrè.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh ojú ìwé 129 sí 130 ìpínrọ̀ 11 àti 12—Ní ṣókí, fi han ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe lè fi JW Library tó wà lórí fóònú tàbí tablet rẹ̀ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 55

 • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library—Apá Kejì: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò méjì tá a pè ní Wa Oríṣiríṣi Ìtumọ̀ Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó àti Ṣe Ìwádìí Nínú Bíbélì Tàbí Ìtẹ̀jáde Míì, kó o sì jíròrò wọ́n ní ṣókí. Lẹ́yìn náà, jíròrò ìsọ̀rí tó gbẹ̀yìn nínú àpilẹ̀kọ náà. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n ti gbà lo JW Library lóde ẹ̀rí.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 16 ìpínrọ̀ 1 sí 15

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 139 àti Àdúrà