Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2016

May 2 sí 8

JÓÒBÙ 38-42

May 2 sí 8
  • Orin 63 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Ní ṣókí, tọ́ka sí àkòrí náà “Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Librarytí ẹ bá ń jíròrò nípa bí ẹ ṣe lè lo fóònú tàbí tablet. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n máa ròyìn iye ìgbà tí wọ́n fi fídíò kan han àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí tó bá di ìparí oṣù. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 60

  • Ǹjẹ́ Ò Ń Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library?”: (15 min.) Kọ́kọ́ fi ìṣẹ́jú márùn-ún jíròrò àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn náà, kó o jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Máa Lo “Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library,” kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, tún jẹ́ kí wọ́n wo àwọn fídíò tá a pè ní Wa Àwọn Ìwé Jáde, Kó O sì Máa Lò Wọ́n àti Máa Lo JW Library Lọ́nà Tó Rọ̀ Ẹ́ Lọ́rùn, kẹ́ ẹ sì jíròrò wọn. Gba àwọn ará níyànjú pé kí àwọn tó bá ní fóònù tàbí tablet tí wọ́n lè fi lo JW Library ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì wa àwọn ìtẹ̀jáde sórí rẹ̀ kó tó di ọ̀sẹ̀ May 16 tá a máa jíròrò apá tá a pè ní “Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library.”

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 14 ìpínrọ̀ 14 sí 22 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 124

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 77 àti Àdúrà