Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 11-18

Ta Ló Lè Jẹ́ Àlejò Nínú Àgọ́ Jèhófà?

Ta Ló Lè Jẹ́ Àlejò Nínú Àgọ́ Jèhófà?

Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àti pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó sì ń ṣègbọràn sí i. Sáàmù ìkẹẹ̀dógún [15] sọ àwọn ohun tí Jèhófà ń wò lára ẹnì kan kó tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

ÀLEJÒ JÈHÓFÀ GBỌ́DỌ̀ . . .

  • jẹ́ oníwà títọ́

  • máa sọ òtítọ́, kódà látinú ọkàn rẹ̀

  • máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi tiẹ̀

  • máa ṣe ohun tó sọ, kódà tó bá tiẹ̀ nira láti ṣe bẹ́ẹ̀

  • máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ láì máa retí ohunkóhun pa dà

ÀLEJÒ JÈHÓFÀ KÒ GBỌ́DỌ̀ . . .

  • jẹ́ olófòófó tàbí afọ̀rọ̀ èké bani jẹ́

  • máa ṣe ohun tí kò dáa sí aládùúgbò rẹ̀

  • máa kó àwọn ará nífà

  • bá àwọn tí kò sin Jèhófà tàbí tí wọ́n ń ṣe àìgbọràn sí i kẹ́gbẹ́

  • gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀