Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  May 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìlérí yìí máa ṣẹ láéláé?

Ka Bíbélì: Iṣi 21:3, 4

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí yìí ṣẹ àti àǹfààní tó máa ṣe fún yín.

ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)

Béèrè ìbéèrè: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wo ìbéèrè yìí. [Fi ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 hàn án àti àwọn ìdáhùn tó wà níbẹ̀.] Kí ni èrò yín nípa rẹ̀?

Ka Bíbélì: Sm 83:18

Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí sọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa orúkọ Ọlọ́run.

BÍBÉLÌ FI KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Àwọn kan rò pé Ọlọ́run ló ń darí ayé. Àmọ́ ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ kọ́ nìyẹn?

Ka Bíbélì: 1Jo 5:19

Fi ìwé lọni: Ìwé yìí ṣe àlàyé tó ṣe kedere nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an lórí kókó yìí àtàwọn kókó míì.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.