Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  March 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Rántí Jèhófà

Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Rántí Jèhófà

Torí pé àwọn Júù ti pa Jèhófà Ọlọ́run wọn tì, Jèhófà rán Jeremáyà pé kó lọ kìlọ̀ nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí wọn. (Jer 13:25) Báwo ni orílẹ̀-èdè náà ṣe dénú ipò yìí? Àwọn ìdílé lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. Ohun tó sì fà á ni pé àwọn olórí ìdílé ò tẹ̀lé ìtọ́ni Jèhófà tó wà nínú Diutarónómì 6:5-7.

Lóde òní, tí ìdílé kọ̀ọ̀kan bá jiná dénú nípa tẹ̀mí, ó máa ń jẹ́ kí ìjọ dúró sán-ún. Àwọn olórí ìdílé lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa rántí Jèhófà nípa ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, kó sì nítumọ̀. (Sm 22:27) Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti wo fídíò ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ —Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, kí ẹ béèrè àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo làwọn ìdílé kan ṣe yanjú ìṣòro tí kì í jẹ́ kí Ìjọsìn Ìdílé wọn lọ déédéé?

  • Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, tó sì nítumọ̀?

  • Tó bá dọ̀rọ̀ Ìjọsìn Ìdílé, kí làwọn ìpènijà tí mo ní, kí ni mo lè ṣe láti yanjú ẹ̀?