Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  March 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 12-16

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì

Jèhófà gbé iṣẹ́ ńlá kan fún Jeremáyà tó máa ṣàpẹẹrẹ ìpinnu tí Jèhófà ṣe láti pa Júdà àti Jerúsálẹ́mù run, torí wọ́n jẹ́ alágídí àti onígbèéraga.

Jeremáyà wá ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ

13:1, 2

  • Ìgbànú tí Jeremáyà so mọ́ ìgbáròkó rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àjọṣe tímọ́tímọ́ tíì bá wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè náà

Jeremáyà mú ìgbànú náà lọ sí Odò Yúfírétì

13:3-5

  • Ó fi í pamọ́ sínú pàlàpálá àpáta gàǹgà, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù

Jeremáyà pa dà sí Odò Yúfírétì láti mú ìgbànú náà

13:6, 7

  • Ìgbànú náà ti bà jẹ́

Jèhófà wá ṣàlàyé fún Jeremáyà ohun tí èyí túmọ̀ sí lẹ́yìn tó ti ṣe ohun tó rán-an

13:8-11

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jeremáyà dá bí ohun tí kò tó nǹkan, síbẹ̀ ìgbọ̀ràn rẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn