• Orin 135 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì”: (10 min.)

  • Jer 13:1-5—Jeremáyà tẹ̀lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún un pé kó tọ́jú ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ̀ kan pa mọ́, àmọ́ iṣẹ́ yìí gba ìsapá gan-an (jr 51 ¶17)

  • Jer 13:6, 7—Nígbà tí Jeremáyà rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn pa dà láti lọ mú ìgbànú náà, ó rí i pé ó ti bà jẹ́ (jr 52 ¶18)

  • Jer 13:8-11—Jèhófà fi èyí ṣàpẹẹrẹ pé àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bà jẹ́ torí pé wọ́n ya alágídí (jr 52 ¶19-20; it-1-E 1121 ¶2)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Jer 12:1, 2, 14—Ìbéèrè wo ni Jeremáyà béèrè, ìdáhùn wo sì ni Jèhófà fún un? (jr 118 ¶11)

  • Jer 15:17—Kí ni ojú ìwòye Jeremáyà nípa yíyan ọ̀rẹ́, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? (w04 5/1 12 ¶16)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 13:15-27

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi àti fídíò—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.

 • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi àti fídíò—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.

 • Àsọyé: (6 min.) w16.03 29-31—Àkòrí: Ìgbà Wo Ni Bábílónì Ńlá Mú Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Nígbèkùn?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI