Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

March 7 sí 13

Ẹ́SÍTÉRÌ 6-10

March 7 sí 13
 • Orin 131 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ẹ́sítérì Kò Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan, Ó Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀”: (10 min.)

  • Ẹst 8:3, 4—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí àwọn ẹlòmíì (ia ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 24 àti 25)

  • Ẹst 8:5—Ẹ́sítérì fọgbọ́n bá Ahasuwérúsì sọ̀rọ̀ (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8)

  • Ẹst 8:17—Ọ̀pọ̀ àwọn ará Páṣíà di aláwọ̀ṣe Júù (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ẹst 8:1, 2—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ kó tó kú pé ‘Bẹ́ńjámínì yóò pín ohun ìfiṣèjẹ ní ìrọ̀lẹ́’ ṣe ṣẹ? (ia ojú ìwé 142, àpótí)

  • Ẹst 9:10, 15, 16—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fàyè gba àwọn Júù láti kó àwọn ìkógun, kí nìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀? (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: Ẹst 8:1-9 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 118

 • Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ara sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní lẹ́yìn tí wọ́n lo ìdánúṣe láti kí àwọn tá a pè sí Ìrántí Ikú Kristi tó kọjá káàbọ̀. Ní kí ẹni tó sọ ìrírí tó gbádùn mọ́ni jù lọ ṣe àṣefihàn ìrírí rẹ̀.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 12 sí 21 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 91 (30 min.)

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 147 àti Àdúrà