Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  March 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 11-15

Jóòbù Gbà Pé Àjíǹde Máa Wà

Jóòbù Gbà Pé Àjíǹde Máa Wà

Jóòbù sọ bó ṣe dá a lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde

14:7-9, 13-15

  • Jóòbù fi ọ̀rọ̀ igi ṣàpèjúwe bó ṣe dá òun lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi ólífì ló ní lọ́kàn

  • Gbòǹgbò igi ólífì máa ń ta gan-an, ó sì máa ń rinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kó tún lè sọjí bí wọ́n tiẹ̀ gé ìtì rẹ̀ lulẹ̀. Tí gbòǹgbò rẹ̀ kò bá ti kú, ó máa hù pa dà

  • Nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dá ti mú kí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, kùkùté igi ólífì tó ti gbẹ lè sọjí pa dà, á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun”