ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí lè ṣe yín láǹfààní?

Ka Bíbélì: Jo 3:16

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí ìyà tí Jésù jẹ àti ikú rẹ̀ ṣe lè ṣe yín láǹfààní.

ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)

Béèrè ìbéèrè: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wo ìbéèrè yìí àti bí àwọn èèyàn ṣe máa ń dáhùn rẹ̀. [Ka ìbéèrè àkọ́kọ́ àtàwọn ìdáhùn tó wà lábẹ́ rẹ̀.] Kí lẹ máa sọ nípa rẹ̀?

Ka Bíbélì: Mt 4:1-4

Fi ìwé lọni: Bí Èṣù ṣe bá Jésù sọ̀rọ̀, tó sì dẹ ẹ́ wò fi hàn pé Èṣù kì í ṣe èrò ibi tó wà lọ́kàn èèyàn. Ohun míì wo ni Bíbélì sọ nípa Èṣù? Àpilẹ̀kọ yìí sọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀.

ÌWÉ ÌKÉSÍNI SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI

Fi ìwé lọni: À ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan. [Fún onílé ní ìwé ìkésíni kan.] Ní March 23, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló máa kóra jọ láti rántí ikú Jésù Kristi, kí wọ́n sì gbọ́ àsọyé Bíbélì kan lọ́fẹ̀ẹ́ tó dá lórí bí ikú Jésù ṣe ṣe wá láǹfààní. Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tá a ti máa ṣe é ládùúgbò wa àti àkókò tó máa wáyé. Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ wá.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.