Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìrántí Ikú Kristi ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Jámánì

ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI–ÌWÉ ÌPÀDÉ March 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2016 lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ́sítérì Fi Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀

Ẹ́sítérì lo ìgboyà, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó sì ti Módékáì lẹ́yìn láti ṣe òfin tó gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ ìparun. (Ẹ́sítérì 6-10)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó O Fẹ́ Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni

Tẹ̀ lé àwọn àbá yìí láti mọ bó o ṣe kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó o fẹ́ lò láti fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀

Báwo la ṣe lè kí àwọn tá a fi ìwé pè àtàwọn aláìṣiṣẹ́ káàbọ̀ sí Ìrántí ikú Kristi?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́ Nígbà Àdánwò

Jóòbù fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. (Jóòbù 1-5)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jóòbù Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀

Ìbànújẹ́ tó lágbára tó bá Jóòbù mú kó ronú lọ́nà tí kò tọ́, àmọ́ ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà kò yingin. (Jóòbù 6-10)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jóòbù Gbà Pé Àjíǹde Máa Wà

Jóòbù gbà pé Ọlọ́run lágbára láti jí òun dìde bí igi tó sọjí pa dà. (Jóòbù 11-15)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìràpadà Mú Kí Àjíǹde Ṣeé Ṣe

Ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà pèsè ló jẹ́ ká nírètí àjíǹde. Dípò ká máa lọ síbi ìsìnkú, a máa ṣètò bí a ó ṣe máa kí àwọn tó ti kú káàbọ̀.