Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà Ṣe Lágbára Tó?

Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà Ṣe Lágbára Tó?

Jóṣúà àti Sólómoni jẹ́rìí sí i pé ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà kò ní lọ láìṣẹ. (Joṣ 23:14; 1Ọb 8:56) Ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ táwọn ẹlẹ́rìí méjì yìí sọ wà lára ìpìlẹ̀ tó lágbára tí àwa náà lè gbé ìgbàgbọ́ wa kà.​—2Kọ 13:1; Tit 1:2.

Báwo ni Jèhófà ṣe mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ nígbà ayé Jóṣúà? A rọ ìwọ àti ìdílé rẹ pé kẹ́ ẹ wo fídíò tí àkọlé rẹ̀ sọ pé ‘Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan Tí Ó Kùnà.’ Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: (1) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ráhábù? (Heb 11:31; Jak 2:​24-26) (2) Báwo ni ọ̀rọ̀ Ákánì ṣe fi hàn pé téèyàn bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, aburú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀? (3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé jagunjagun ni àwọn ará Gíbéónì, kí nìdí tí wọ́n fi tan Jóṣúà tí wọ́n sì wá àlàáfíà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (4) Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe nímùúṣẹ nígbà tí àwọn ọba Ámórì márùn-ún ń halẹ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (Joṣ 10:​5-14) (5) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà gbèjà rẹ bó o ṣe ń fi Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́?​—Mt 6:33.

Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe, àwọn ohun tó ń ṣe báyìí àtàwọn tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìlérí rẹ̀ á máa lágbára sí i.​—Ro 8:31, 32.

Ǹjẹ́ o ní ìgbàgbọ́ bíi ti Jóṣúà?