Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

June 5-​11

JEREMÁYÀ 51-52

June 5-​11
 • Orin 37 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Gbogbo Ọ̀rọ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ Láìkù Síbì Kan”: (10 min.)

  • Jer 51:​11, 28​—Jèhófà sọ ẹni tó máa pa Bábílónì run (it-2 360 ¶2-3)

  • Jer 51:30​—Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì ò ní lè ṣe nǹkan kan nígbà táwọn ọ̀tá bá wá pa ìlú wọn run (it-2 459 ¶4)

  • Jer 51:​37, 62​—Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bábílónì máa dahoro nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín (it-1 237 ¶1)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Jer 51:25​—Kí nìdí tí Bábílónì fi jẹ́ “òkè ńlá tí ń fa ìparun”? (it-2 444 ¶9)

  • Jer 51:42​—Kí ni “òkun” tó máa ‘wá sórí Bábílónì’? (it-2 882 ¶3)

  • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

  • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 51:1-11

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa fi ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì jw.org han onílé, lábẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI