Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 6-10

Ṣé O Máa Wà Lára Àwọn Tá A Máa Sàmì Sí Láti Là Á Já?

Ṣé O Máa Wà Lára Àwọn Tá A Máa Sàmì Sí Láti Là Á Já?

Ìran ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ pa run. Báwo ni ìran yẹn ṣe máa ṣẹ lóde òní?

9:​1, 2

  • Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi

  • Àwọn ọkùnrin mẹ́fà tó ní àwọn ohun ìjà tó lè fọ́ nǹkan túútúú ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ogun ọ̀run, Kristi tó jẹ́ olórí wọn sì wà pẹ̀lú wọn

9:3-7

  • Lákòókò tí ìpọ́njú ńlá bá ń lọ lọ́wọ́, Jésù máa ṣe ìdájọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, ó sì máa sàmì sí wọn pé wọ́n jẹ́ àgùntàn

Kí ló yẹ kí n ṣe kí n bàa lè wà lára àwọn tí Jésù máa sàmì sí láti là á já?