Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Ìlànà Jèhófà Nínú Ìwà àti Ìṣe Rẹ

Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Ìlànà Jèhófà Nínú Ìwà àti Ìṣe Rẹ

Jèhófà fún àwa èèyàn ní ìlànà nípa ìwà tó yẹ ká máa hù. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ pé kí ọkọ àti ìyàwò wà pọ̀ títí láé. (Mt 19:​4-6, 9) Ó kórìíra ìṣekúṣe èyíkéyìí. (1Kọ 6:​9, 10) Ó tún fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àwọn ìlànà nípa aṣọ àti ìmúra, kí wọ́n bàa lè yàtọ̀ sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tó kù.​—Di 22:5; 1Ti 2:​9, 10.

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. (Ro 1:​18-32) Ìlànà táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra, ìwọṣọ àti ìwà wọn. Ọ̀pọ̀ kì í tijú láti hùwà tó burú jáì, wọ́n sì tún máa ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn tí kò hùwà bíi tiwọn.​—1Pe 4:​3, 4.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú ìwà àti ìṣe wa. (Ro 12:9) Síbẹ̀, kò yẹ ká máa kan àwọn èèyàn lábùkù nígbà tá a bá ń sọ ohun tí Jèhófà fẹ́ fún wọn. Ó tún yẹ kí ìgbé ayé wa fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń yan irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé ìlànà Jèhófà ni aṣọ àti ìmúra mi ń gbé yọ àbí ìlànà ti ayé? Ṣé aṣọ àti ìmúra mi fi hàn pé Kristẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni mí?’ Tó bá sì jẹ́ pé ètò tẹlifíṣọ̀n tàbí fídíò kan la fẹ́ wò, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé inú Jèhófà dùn sí irú ètò tàbí fídíò yìí? Ìlànà ta ló ń gbé lárugẹ? Ṣé eré ìnàjú tí mò ń ṣe kò lè mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí kò dára? (Sm 101:3) Ṣé kò lè mú àwọn ìdílé mi tàbí àwọn míì kọsẹ̀?’​—1Kọ 10:​31-33.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà tó yẹ ká máa hù? Kristi Jésù máa tó wá pa àwọn ẹni ibi run ní gbogbo orílẹ̀-èdè. (Isk 9:​4-7) Àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìkan ló máa kù láyé. (1Jo 2:​15-17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìwà àti ìṣe wa, kí àwọn tó ń kíyè sí ìwà rere wa lè fi ògo fún Ọlọ́run.​—1Pe 2:​11, 12.

Tí mo bá wọ aṣọ yìí tàbí tí mo múra báyìí, irú èèyàn wo ni àwọn èèyàn máa kà mí sí?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ​—ỌKỌ KAN, AYA KAN, LẸ́YÌN NÁÀ KÓ O DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà?

  • Kí nìdí tó fi dára kí àwọn òbí ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré nípa ìwà tí Jèhófà fẹ́ ká máa hù?

  • Báwo ni tọmọdé-tàgbà wa ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní oore Ọlọ́run?