Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìwàásù Ìhìn Rere Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìwàásù Ìhìn Rere Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Ṣé ó ti ṣòro fún ẹ rí láti wàásù? Ká sòótọ́, ìwàásù kì í yá ọ̀pọ̀ nínú wa lára nígbà míì. Kí nìdí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa, bóyá wọ́n máa ń ta kò wá tàbí ẹ̀rù máa ń bà wá láti bá àwọn tá ò mọ̀ sọ̀rọ̀. Ó dájú pé àwọn nǹkan yìí lè paná ayọ̀ wa. Síbẹ̀, Ọlọ́run aláyọ̀ là ń sìn, ó sì fẹ́ ká máa fi ayọ̀ jọ́sìn òun. (Sm 100:2; 1Ti 1:11) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí pàtàkì mẹ́ta tó fi yẹ ká máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Àkọ́kọ́, ìwàásù wa ń fún àwọn èèyàn ní ìrètí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìrètí àwọn èèyàn ń kú lọ nínú ayé, a lè fi “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” kún inú ọkàn wọn. (Ais 52:7) Àmọ́, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń fún àwa náà ní ayọ̀. Ká tó jáde lọ wàásù, ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Ìkejì, ìhìn rere tí à ń wàásù ń ṣe àwọn èèyàn ní àǹfààní nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí. Ó ń mú kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ìwàkíwà, kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ais 48:​17, 18; Ro 1:16) Iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà. Bí àwọn míì kò bá tiẹ̀ fẹ́ kí á gba àwọn là, a ó máa bá a nìṣó láti wá àwọn tó ń fẹ́ ìgbàlà.​—Mt 10:​11-14.

Ìdí kẹta tó sì ṣe pàtàkì jù ni pé, ìwàásù wa ń fi ògo fún Jèhófà. Ó mọyì iṣẹ́ ìwàásù wa gan-an. (Ais 43:10; Heb 6:10) Ó tún máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fàlàlà ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣe tán, ayọ̀ jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí. (Ga 5:22) Ó dájú pé Jèhófà lè mú ká borí àwọn ìṣòro wa, ká sì máa fi ìgboyà wàásù. (Iṣe 4:31) Yálà àwọn èèyàn tẹ́tí sí wa tàbí wọ́n ta kò wá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, a ó máa fi ayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́.​—Isk 3:3.

Irú ìmọ̀lára wo ló wù ẹ́ kó o ní tó o bá wà lóde ẹ̀rí? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o láyọ̀?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, WÀÁ LÁYỌ̀ TÓ O BÁ Ń KẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ O SÌ Ń ṢÀṢÀRÒ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kódà tá a bá tiẹ̀ ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù lóṣooṣù?

  • Báwo la ṣe lè fara wé Màríà?

  • Ìgbà wo lo máa ń wáyè láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí o sì ṣàṣàrò lé e lórí?

  • Kí ló máa ń fún ẹ láyọ̀ tó o bá ń wàásù ìhìn rere?