Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 1-5

Inú Ìsíkíẹ́lì Dùn Láti Kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Inú Ìsíkíẹ́lì Dùn Láti Kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún un ní àkájọ ìwé kan, ó sì sọ pé kó jẹ ẹ́. Kí ni ìtúmọ̀ ìran yẹn?

2:9–3:2

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ yé Ìsíkíẹ́lì dáadáa. Tó bá ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkájọ ìwé náà, ó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, èyí á sì jẹ́ kó nígboyà láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

3:3

  • Àkájọ ìwé náà dùn lẹ́nu Ìsíkíẹ́lì, torí pé inú rẹ̀ dùn sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un

Àǹfààní wo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́, àdúrà àti àṣàrò lè ṣe fún mi?

 

Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ máa fún mi láyọ̀?