Kí ló ran Jeremáyà lọ́wọ́ tó fi fara da ìṣòro tó lágbára gan-an, tí kò sì ṣìwà hù?

3:​20, 21, 24, 26, 27

  • Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà máa “tẹ̀ ba mọ́lẹ̀” nítorí àwọn tó ti ronú pìwà dà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì máa mú ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn wọn

  • Ó ti kọ́ láti “ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.” Tí ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fara da àdánwò ìgbàgbọ́ láti ìgbà ọ̀dọ́, ńṣe ni èyí á mú kó rọrùn fún un láti kojú àwọn ìṣòro tó ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú

Báwo ni mo ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

 

Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn?