Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2017

June 12-​18

ÌDÁRÒ 1-5

June 12-​18
 • Orin 128 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Jẹ́ Ká Ní Ìfaradà”: (10 min.)

  • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìdárò.]

  • Ida 3:​20, 21, 24​—Jeremáyà fi hàn pé òun ní ẹ̀mí ìdúródeni, ó sì gbẹ̀kẹ̀ lé Jèhófà (w12 6/1 14 ¶3-4; w11 9/15 8 ¶8)

  • Ida 3:​26, 27​—Tá a bá ń fara da àdánwò ìgbàgbọ́ ní báyìí, èyí á jẹ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro tó ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú (w07 6/1 11 ¶4-5)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ida 2:17​—“Àsọjáde” wo ní pàtàkì ni Jèhófà mú ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù? (w07 6/1 9 ¶4)

  • Ida 5:7​—Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń mú káwọn èèyàn jìyà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn baba ńlá wọn ṣẹ̀? (w07 6/1 11 ¶1)

  • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

  • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ida 2:20–3:12

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI