Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 34-37

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere

“Má ṣe ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo”

37:1, 2

  • Má ṣe jẹ́ kí àṣeyọrí tí kì í tọ́jọ́ táwọn ẹni burúkú ṣe mú kó o ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìbùkún tẹ̀mí àtàwọn àfojúsùn tẹ̀mí

“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”

37:3

  • Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà máa ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o bá ń ṣàníyàn tàbí ṣiyèméjì. Ó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀

  • Máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run

“Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà”

37:4

  • Ṣètò àkókò rẹ láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà lọ́nà tí wàá fi lè túbọ̀ mọ Jèhófà

‘Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́’

37:5, 6

  • Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bójú tó ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní

  • Máa hùwà tó dára kódà tí wọ́n bá ń ta kò ọ́, tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí ọ tàbí tí wọ́n ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa rẹ

“Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà, kí o sì fi ìyánhànhàn dúró dè é”

37:7-9

  • Yẹra fún fífi ìwàǹwára ṣe nǹkan. Ó lè ba ayọ̀ rẹ jẹ́, ó sì lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé”

37:10, 11

  • Túbọ̀ máa jẹ́ ọkàn tútù, kó o sì fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró de Jèhófà títí tó fi máa mú gbogbo àìṣèdájọ́-òdodo tí wọ́n ṣe sí ọ kúrò

  • Máa ṣètìlẹ́yìn fáwọn onígbàgbọ́ bíi tìẹ, kó o sì máa fi ìlérí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣe, tí kò ní pẹ́ dé mọ́ tu àwọn tó sorí kọ́ nínú

Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni Ìjọba Mèsáyà máa mú wá