Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:

Fídíò máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an torí pé wọ́n lè rí àwòrán, wọ́n á sì tún gbọ́ ohùn. Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n pọkàn pọ̀, wọn ò sì lè tètè gbà gbé ohun tí wọ́n bá wò. Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ lílo ohun tó ṣeé fojú rí láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.Iṣe 10:9-16; Iṣi 1:1.

A ṣe fídíò Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?, Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì? àti Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ bá dé ẹ̀kọ́ 2 àti 3 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀. Fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?, Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? àti Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? la fi ń gba àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ níyànjú pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa tàbí ká fi pè wọ́n wá sáwọn ìpàdé wa. A lè fi àwọn fídíò wa tó gùn díẹ̀ kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́.km 5/13 ojú ìwé 3.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Wa fídíò tó o fẹ́ fi han onílé jáde kó o tó lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́

  • Múra ìbéèrè kan tàbí méjì sílẹ̀ tí fídíò náà máa dáhùn

  • Ẹ jọ wo fídíò náà pa pọ̀

  • Ẹ jíròrò àwọn kókó pàtàkì inú rẹ̀

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ:

  • Fi ẹ̀yìn ọ̀kan lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa han onílé, kó o sì ní kó wo àmì ìlujá tó wà níbẹ̀ táá jẹ́ kó lè wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  • Jẹ́ kí onílé wo fídíò Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? kó o sì fún un ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, fi ẹ̀kọ́ 3 hàn án