Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ọlọ́run Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”

“Ọlọ́run Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”

Ìwé Sáàmù 52-59 jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára Dáfídì láwọn ìgbà tó ní ìṣòro. Àmọ́, ó ṣì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láwọn àkókò tí nǹkan kò rọrùn fún un yẹn. (Sm 54:4; 55:22) Ó tún yin Jèhófà nítorí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. (Sm 56:10) Ǹjẹ́ àwa náà ń sapá láti ní irú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run? Ṣé a máa ń wá ìtọ́sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ní ìṣòro? (Owe 2:6) Ẹsẹ Bíbélì wo ló ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o . . .

  • ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí soríkọ́?

  • ṣàìsàn?

  • tí ẹnì kan ṣe ohun tó dùn ọ́?

  • tí wọ́n ṣe inúnibíni sí ọ?