Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  June 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 52-59

“Ju Ẹrù Ìnira Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà”

“Ju Ẹrù Ìnira Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà”

Dáfídì kojú ọ̀pọ̀ àdánwò tó le koko nígbèésí ayé rẹ̀. Nígbà tó kọ Sáàmù 55, ó ti kojú àwọn ìṣòro bí . . .

  • Ọ̀rọ̀ Kòbákùngbé

  • Inúnibíni

  • Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Lágbára

  • Àjálù

  • Àìsàn

  • Ìwà Ọ̀dàlẹ̀

Kódà nígbà tó dà bíi pé ẹrù ìnira yẹn kọjá agbára Dáfídì, ó ṣì fara dà á. Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti fún àwọn tó nírú ìṣòro yìí ni: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”

Báwo la ṣe lè fi ohun tí ẹsẹ yìí sọ sílò lóde òní?

55:22

  1. Ká máa sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ìṣòro èyíkéyìí tàbí àníyàn ọkàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà

  2. Ká máa wá ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀

  3. Ká máa ṣe ohun tá a bá lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì