Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 21-23

Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí

Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Jésù ni ẹni tí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọba tọ́ sí “lọ́nà òfin.”

  • Jẹ 49:10

    Láti inú ẹ̀yà wo ni Mèsáyà ti wá?

  • 2Sa 7:12, 16

    Ta ni Jèhófà sọ fún pé ìjọba rẹ̀ máa wà títí láé?

  • Mt 1:16

    Láti apá ọ̀dọ̀ ta ni Mátíù ti ṣàlàyé ìlà ìdílé tí wọ́n ti máa bí Jésù láti fi hàn pé ó lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì?

Kí lo rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe fìdí ìjọba Jésù múlẹ̀ lọ́nà òfin?