Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn ará ń wàásù láti ilé dé ilé ní orílẹ̀-èdè Ítálì

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI July 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti láti kọ́ni nípa ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ṣé O Máa Ń Jẹ́ Kí Jèhófà Tọ́ Ẹ Sọ́nà?

Kí ni ọkàn wa ní í ṣe pẹ̀lú eré ìnàjú tá à ń ṣe pẹ̀lú aṣọ àti ìmúra wa? Kí ló túmọ̀ sí láti ní ọkàn-àyà ẹlẹ́ran ara?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ṣé O Máa Ń Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ?

Kí la rí kọ́ lára Ọba Sedekáyà nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí kò bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Tí Jèhófà Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?

Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó fi bí Jèhófà ṣe máa ń dari jini tó hàn? Báwo ni ọ̀nà tó gbà bá Dáfídì, Mánásè àti Pétérù lò ṣe fi hàn pé ó máa ń dárí jini pátápátá?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Máa Ń Dárí Ji Ara Rẹ?

Ó sábà máa ń ṣòro lati dárí ji ara wa torí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, kódà tí Jehófà bá tiẹ̀ ti dárí jì wá. Kí la lè ṣe?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí

Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa ọba tó lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin ṣe ṣẹ sí Jésù lára? Kí ni èyí kọ wa nípa Jèhófà Ọlọ́run?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Hùwà Tó Bójú Mu Lóde Ẹ̀rí

Nígbà tá a bá wà lẹ́nu ilẹ̀kùn àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí, a lè má mọ̀ pé àwọn onílé ń wò wá tàbí kí wọ́n máa gbọ́ wa. Báwo la ṣe lè máa hùwà tó bójú mu lóde ẹ̀rí?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Ìlú Tírè Ṣe Máa Pa Run Mú Ká Fọkàn Tán Ọ̀rọ̀ Jèhófà

Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa bí ìlú Tírè ṣe máa pa run ní ìmúṣẹ láìkùsíbì kan.