Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 60-68

Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà

Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà

Tó o bá ṣèlérí fún Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ

61:1, 8

  • Tó o bá ń gbàdúrà nípa àwọn ìlérí tó o ṣe, Jèhófà á fún ẹ lókun kó o lè mú un ṣẹ

  • Bí a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ṣe

Hánà

Tó o bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e

62:8

  • Kí àdúrà wa lè nítumọ̀, a ní láti máa sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà

  • Tí àdúrà wa bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà wa á ṣe kedere sí wa

Jésù

Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere

65:1, 2

  • Jèhófà máa ń tẹ́tí sí “àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo” tó fẹ́ mọ̀ ọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀

  • Ìgbàkigbà la lè gbàdúrà sí Jèhófà

Kọ̀nílíù

Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ fi sínú àdúrà mi.