Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 79-86

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì tó ń jẹ́ Ásáfù ló kọ Sáàmù 83, ó sì gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Dáfídì Ọba. Àkókò tí àwọn orílẹ̀-èdè gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ ló kọ sáàmù yìí.

83:1-5, 16

  • Kàkà tí ì bá fi máa gbàdúrà nípa ààbò ti ara rẹ̀, ohun tí àdúrà rẹ̀ dá lé ni orúkọ Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀

  • Lóde òní, ìgbà gbogbo làwọn èèyàn ń ta ko àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, tá a sì ń lo ìfaradà ńṣe là ń bọlá fún Jèhófà

83:18

  • Jèhófà fẹ́ ká mọ orúkọ òun

  • O yẹ kó máa hàn nínú ìwà àti ìṣe wa pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa