Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2016

July 25 sí 31

SÁÀMÙ 79-86

July 25 sí 31
 • Orin 138 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?”: (10 min.)

  • Sm 83:1-5—Orúkọ Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ (w08 10/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 7 àti 8)

  • Sm 83:16—Ìdúróṣinṣin àti ìfaradà wa ń bọlá fún Jèhófà (w08 10/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16)

  • Sm 83:17, 18—Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run (w11 5/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 àti 2; w08 10/15 ojú ìwé 15 àti 16 ìpínrọ̀ 17 àti 18)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Sm 79:9—Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn àdúrà wa? (w06 7/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 5)

  • Sm 86:5—Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà “ṣe tán láti dárí jini”? (w06 7/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 85:8–86:17

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 111

 • Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ? yìí, ó wà lórí ìkànnì jw.org. (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ. Lẹ́yìn náà, lọ síbi tí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ wà, kó o sì ṣí i. Wàá rí fídíò náà lábẹ́ ẹ̀kọ́ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ta Ni Ọlọ́run?”) Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo la ṣe lè lo fídíò yìí tá a bá ń jẹ́rìí fún àwọn èèyàn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, níbi tí àwọn èèyàn pọ̀ sí àti láti ilé-dé-ilé? Àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni wo lẹ ní nígbà tẹ́ ẹ lo fídíò yìí?

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 20 ìpínrọ̀ 14 sí 26 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 179

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 143 àti Àdúrà

  Ìránnilétí: Jọ̀wọ́ jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.