Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 74-78

Máa Rántí Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà

Máa Rántí Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà

Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe

74:16; 77:6, 11, 12

 • Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí dáadáa

 • Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa Jèhófà, a ò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣèlérí fún wa

Ara àwọn iṣẹ́ Jèhófà ni:

74:16, 17; 75:6, 7; 78:11-17

 • Àwọn ohun tó dá

  Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe túbọ̀ máa rí i pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba

 • Àwọn ọkùnrin tó yàn láti máa bójú tó ìjọ

  Ó yẹ ká máa tẹrí ba fún àwọn tí Jèhófà yàn láti máa múpò iwájú nínú ètò rẹ̀

 • Bó ṣe ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ là

  Tá a bá ń rántí bí Jèhófà ṣe ń gbà àwọn èèyàn rẹ̀ là, èyí á fún ìgbàgbọ́ wa lókun pé ó wu Jèhófà láti bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀