Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé

Kéèyàn tó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó gbọ́dọ̀ ní ètò tó dáa. O lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó o bá lè máa ní wákàtí méjìdínlógún [18] lọ́sẹ̀, wàá sì tún ráyè fún àwọn nǹkan míì! Kódà, wákàtí rẹ ṣì lè máa pé táwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ bá tiẹ̀ yọjú, irú bí àìsàn tàbí ojú ọjọ́ tí kò dáa. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí fi hàn bí àwọn akéde ṣe lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, bóyá wọ́n ń fi àkókò díẹ̀ ṣiṣẹ́ tàbí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún àkókò tó pọ̀ títí kan àwọn tó ní àìlera. Tẹ́ ẹ bá ṣe àwọn àyípadà kan, ẹnì kan nínú ìdílé yín lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lóṣù September. Ó máa dáa tẹ́ ẹ bá lè jíròrò rẹ̀ nígbà ìjọsìn ìdílé yín tó kàn.

ÀKÓKÒ DÍẸ̀ NI MO FI Ń ṢIṢẸ́

Monday

IṢẸ́

Tuesday

IṢẸ́

Wednesday

IṢẸ́

Thursday

wákàtí 6

Friday

wákàtí 6

Saturday

wákàtí 4

Sunday

wákàtí 2

ÀKÓKÒ TÓ PỌ̀ NI MO FI Ń ṢIṢẸ́

Monday

wákàtí 2

Tuesday

wákàtí 2

Wednesday

ÌPÀDÉ ÀÁRÍN Ọ̀SẸ̀

Thursday

wákàtí 2

Friday

wákàtí 2

Saturday

wákàtí 6

Sunday

wákàtí 4

MO NÍ ÀÌLERA

Monday

SINMI

Tuesday

wákàtí 3

Wednesday

wákàtí 3

Thursday

wákàtí 3

Friday

wákàtí 3

Saturday

wákàtí 3

Sunday

wákàtí 3