Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 69-73

Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́

Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́

Ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé lóòótọ́ la jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́

69:9

  • Dáfídì ní ìtara fún ìjọsìn Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀

  • Dáfídì kò gbà kí ẹnikẹ́ni bá Jèhófà díje tàbí kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà

Àwọn àgbàlagbà lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ onítara

71:17, 18

  • Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì ló kọ sáàmù yìí. Ó sọ pé ó wu òun láti fún àwọn ìran tó ń bọ̀ ní ìṣírí

  • Àwọn òbí àtàwọn Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lè dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́

Ìtara ló ń jẹ́ ká sọ fún àwọn èèyàn nípa nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé

72:3, 12, 14, 16-19